-
Nọ́ńbà 25:11-13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 “Fíníhásì+ ọmọ Élíásárì ọmọ àlùfáà Áárónì ti jẹ́ kí inú tó ń bí mi sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rọlẹ̀ torí pé kò fàyè gba bíbá mi díje rárá láàárín wọn.+ Ìdí nìyẹn ti mi ò fi pa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì run bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo sọ fún wọn pé èmi nìkan ṣoṣo ni wọ́n gbọ́dọ̀ máa sìn.+ 12 Torí náà, sọ pé, ‘Màá bá a dá májẹ̀mú àlàáfíà. 13 Yóò sì jẹ́ májẹ̀mú iṣẹ́ àlùfáà tó máa wà pẹ́ títí fún òun àti àtọmọdọ́mọ rẹ̀,+ torí pé kò fàyè gba bíbá Ọlọ́run+ rẹ̀ díje, ó sì ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.’”
-