-
Diutarónómì 7:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 “Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá mú ọ dé ilẹ̀ tí o fẹ́ wọ̀ tí o sì máa gbà,+ ó máa mú àwọn orílẹ̀-èdè tí èèyàn wọn pọ̀ kúrò níwájú rẹ:+ àwọn ọmọ Hétì, àwọn Gẹ́gáṣì, àwọn Ámórì,+ àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì,+ àwọn orílẹ̀-èdè méje tí èèyàn wọn pọ̀ tí wọ́n sì lágbára jù ọ́ lọ.+ 2 Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́, wàá sì ṣẹ́gun wọn.+ Kí o rí i pé o pa wọ́n run pátápátá.+ O ò gbọ́dọ̀ bá wọn dá májẹ̀mú kankan, o ò sì gbọ́dọ̀ ṣojúure sí wọn rárá.+
-