ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 68:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  6 Ọlọ́run ń fún àwọn tó dá wà ní ilé tí wọ́n á máa gbé;+

      Ó ń mú àwọn ẹlẹ́wọ̀n jáde wá sínú aásìkí.+

      Àmọ́ ilẹ̀ gbígbẹ ni àwọn alágídí* yóò máa gbé.+

  • Sáàmù 146:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Ẹni tó ń ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn tí wọ́n lù ní jìbìtì,

      Ẹni tó ń fún àwọn tí ebi ń pa lóúnjẹ.+

      Jèhófà ń dá àwọn ẹlẹ́wọ̀n* sílẹ̀.+

  • Àìsáyà 49:8, 9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  8 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

      “Mo dá ọ lóhùn ní àkókò ojúure,*+

      Mo sì ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ọjọ́ ìgbàlà;+

      Mò ń ṣọ́ ọ kí n lè fi ọ́ ṣe májẹ̀mú fún àwọn èèyàn náà,+

      Láti tún ilẹ̀ náà ṣe,

      Láti mú kí wọ́n gba àwọn ohun ìní wọn tó ti di ahoro,+

       9 Láti sọ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n pé, ‘Ẹ jáde wá!’+

      Àti fún àwọn tó wà nínú òkùnkùn+ pé, ‘Ẹ fara hàn!’

      Etí ọ̀nà ni wọ́n ti máa jẹun,

      Ojú gbogbo ọ̀nà tó ti bà jẹ́* ni wọ́n ti máa jẹko.

  • Àìsáyà 61:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 61 Ẹ̀mí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wà lára mi,+

      Torí Jèhófà ti yàn mí kí n lè kéde ìhìn rere fún àwọn oníwà pẹ̀lẹ́.+

      Ó rán mi láti di ọgbẹ́ àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn,

      Láti kéde òmìnira fún àwọn ẹrú,

      Pé ojú àwọn ẹlẹ́wọ̀n sì máa là rekete,+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́