ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 2:8, 9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  8 Béèrè lọ́wọ́ mi, màá fi àwọn orílẹ̀-èdè ṣe ogún fún ọ

      Màá sì fi gbogbo ìkángun ayé ṣe ohun ìní fún ọ.+

       9 Wàá fi ọ̀pá àṣẹ onírin+ ṣẹ́ wọn,

      Wàá sì fọ́ wọn túútúú bí ìkòkò amọ̀.”+

  • Sáàmù 45:4, 5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Nínú ọlá ńlá rẹ, kí o ṣẹ́gun;*+

      Máa gẹṣin lọ nítorí òtítọ́ àti ìrẹ̀lẹ̀ àti òdodo,+

      Ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì ṣe* àwọn ohun àgbàyanu.

       5 Àwọn ọfà rẹ mú, wọ́n ń mú kí àwọn èèyàn ṣubú níwájú rẹ;+

      Wọ́n ń gún ọkàn àwọn ọ̀tá ọba.+

  • Mátíù 28:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Jésù sún mọ́ wọn, ó sì sọ fún wọn pé: “Gbogbo àṣẹ ní ọ̀run àti ayé la ti fún mi.+

  • Ìfihàn 6:2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 Sì wò ó! mo rí ẹṣin funfun kan,+ ẹni tó jókòó sórí rẹ̀ ní ọfà* kan; a sì fún un ní adé,+ ó jáde lọ, ó ń ṣẹ́gun, kó lè parí ìṣẹ́gun rẹ̀.+

  • Ìfihàn 12:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 Obìnrin náà sì bí ọmọ kan,+ ọkùnrin ni, ẹni tó máa fi ọ̀pá irin+ ṣe olùṣọ́ àgùntàn gbogbo orílẹ̀-èdè. A sì já ọmọ náà gbà lọ* sọ́dọ̀ Ọlọ́run àti síbi ìtẹ́ rẹ̀.

  • Ìfihàn 19:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Mo rí i tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, wò ó! ẹṣin funfun kan.+ A pe ẹni tó jókòó sórí rẹ̀ ní Ẹni Tó Ṣeé Gbára Lé+ àti Olóòótọ́,+ ó ń ṣèdájọ́, ó sì ń fi òdodo+ jagun lọ.

  • Ìfihàn 19:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Idà tó mú, tó sì gùn jáde láti ẹnu rẹ̀,+ kó lè fi pa àwọn orílẹ̀-èdè, ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn.+ Bákan náà, ó ń tẹ ìbínú àti ìrunú Ọlọ́run Olódùmarè níbi tí a ti ń fún wáìnì.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́