15 Torí ohun tí Ẹni Gíga àti Ẹni Tó Ta Yọ sọ nìyí,
Tó wà láàyè títí láé,+ tí orúkọ rẹ̀ sì jẹ́ mímọ́:+
“Ibi gíga àti ibi mímọ́ ni mò ń gbé,+
Àmọ́ mo tún ń gbé pẹ̀lú àwọn tí a tẹ̀ rẹ́, tí wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì ní ẹ̀mí,
Láti mú kí ẹ̀mí ẹni tó rẹlẹ̀ sọ jí,
Kí n sì mú kí ọkàn àwọn tí a tẹ̀ rẹ́ sọ jí.+