ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 135:15-18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè jẹ́ fàdákà àti wúrà,

      Iṣẹ́ ọwọ́ èèyàn.+

      16 Wọ́n ní ẹnu, àmọ́ wọn ò lè sọ̀rọ̀;+

      Wọ́n ní ojú, àmọ́ wọn ò lè ríran;

      17 Wọ́n ní etí, àmọ́ wọn ò lè gbọ́ràn.

      Kò sí èémí kankan ní ẹnu wọn.+

      18 Àwọn tó ń ṣe wọ́n yóò dà bíi wọn gẹ́lẹ́,+

      Bẹ́ẹ̀ ló sì ṣe máa rí fún gbogbo àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé wọn.+

  • Àìsáyà 40:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Oníṣẹ́ ọnà ṣe ère,*

      Oníṣẹ́ irin fi wúrà bò ó,+

      Ó sì fi fàdákà rọ ẹ̀wọ̀n.

  • Àìsáyà 46:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  6 Àwọn kan wà tó ń kó wúrà jáde yàlàyòlò látinú àpò wọn;

      Wọ́n ń wọn fàdákà lórí òṣùwọ̀n.

      Wọ́n gba oníṣẹ́ irin síṣẹ́, ó sì fi ṣe ọlọ́run.+

      Wọ́n wá wólẹ̀, àní, wọ́n jọ́sìn rẹ̀.*+

  • Jeremáyà 10:3, 4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  3 Àṣà àwọn èèyàn náà jẹ́ ẹ̀tàn.*

      Igi igbó lásán ni wọ́n gé lulẹ̀,

      Ohun tí oníṣẹ́ ọnà fi irin iṣẹ́* gbẹ́ ni.+

       4 Fàdákà àti wúrà ni wọ́n fi ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́+

      Òòlù* àti ìṣó ni wọ́n fi kàn án mọ́lẹ̀ kó má bàa ṣubú.+

  • Jeremáyà 10:8, 9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  8 Gbogbo wọn jẹ́ aláìnírònú àti òmùgọ̀.+

      Ìmọ̀ràn látọ̀dọ̀ igi jẹ́ kìkìdá ẹ̀tàn.*+

       9 Àwọn fàdákà pẹlẹbẹ tí wọ́n kó wá láti Táṣíṣì+ àti wúrà láti Úfásì,

      Ohun tí oníṣẹ́ ọnà ṣe àti ohun tí oníṣẹ́ irin ṣe.

      Aṣọ wọn jẹ́ fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti òwú aláwọ̀ pọ́pù.

      Gbogbo wọn jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọ̀jáfáfá.

  • Ìṣe 19:26
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 26 Ní báyìí, ẹ ti rí i, ẹ sì ti gbọ́ bí Pọ́ọ̀lù yìí ṣe yí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lérò pa dà, tó sì mú kí wọ́n ní èrò míì, kì í ṣe ní Éfésù nìkan,+ àmọ́ ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ní gbogbo ìpínlẹ̀ Éṣíà, tó ń sọ pé àwọn ọlọ́run tí a fi ọwọ́ ṣe kì í ṣe ọlọ́run.+

  • 1 Kọ́ríńtì 10:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Kí ni mo wá ń sọ? Ṣé pé ohun tí a fi rúbọ sí òrìṣà jẹ́ nǹkan kan tàbí pé òrìṣà jẹ́ nǹkan kan ni?

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́