ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́sírà 3:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn kọrin,+ wọ́n ń yin Jèhófà, wọ́n sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, “nítorí ó jẹ́ ẹni rere; ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ní sí Ísírẹ́lì sì wà títí láé.”+ Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn èèyàn kígbe sókè láti yin Jèhófà nítorí wọ́n ti fi ìpìlẹ̀ ilé Jèhófà lélẹ̀.

  • Sáàmù 106:47
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 47 Gbà wá, Jèhófà Ọlọ́run wa,+

      Kí o sì kó wa jọ látinú àwọn orílẹ̀-èdè+

      Ká lè máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ,

      Ká sì máa yọ̀ bí a ṣe ń yìn ọ́.*+

  • Àìsáyà 49:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Ẹ kígbe ayọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, sì máa yọ̀, ìwọ ayé.+

      Kí inú àwọn òkè dùn, kí wọ́n sì kígbe ayọ̀.+

      Torí Jèhófà ti tu àwọn èèyàn rẹ̀ nínú,+

      Ó sì ń ṣàánú àwọn èèyàn rẹ̀ tí ìyà ń jẹ.+

  • Jeremáyà 31:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Wọ́n á wá, wọ́n á sì kígbe ayọ̀ ní ibi gíga Síónì+

      Inú wọn á dùn nítorí oore* Jèhófà,

      Nítorí ọkà àti wáìnì tuntun+ pẹ̀lú òróró,

      Nítorí àwọn ọmọ inú agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran.+

      Wọ́n* á dà bí ọgbà tí a bomi rin dáadáa,+

      Wọn kò sì ní ráágó mọ́.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́