ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 49:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Sí Édómù, ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí:

      “Ṣé kò sí ọgbọ́n mọ́ ní Témánì ni?+

      Ṣé kò sí ìmọ̀ràn rere mọ́ lọ́dọ̀ àwọn olóye ni?

      Ṣé ọgbọ́n wọn ti jẹrà ni?

  • Ìdárò 4:22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ti dòpin, ìwọ ọmọbìnrin Síónì.

      Ẹnikẹ́ni kò ní gbé ọ lọ sí ìgbèkùn mọ́.+

      Àmọ́ Ọlọ́run yóò fiyè sí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, ìwọ ọmọbìnrin Édómù.

      Yóò tú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ síta.+

  • Ìsíkíẹ́lì 25:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Édómù ti gbẹ̀san lára ilé Júdà, wọ́n sì ti jẹ̀bi gidigidi torí ẹ̀san tí wọ́n gbà;+

  • Ọbadáyà 10-13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Nítorí ìwà ìkà tí o hù sí Jékọ́bù ọmọ ìyá rẹ,+

      Ojú yóò tì ọ́,+

      Ìwọ yóò sì ṣègbé títí láé.+

      11 Ní ọjọ́ tí ìwọ ta kété sí ẹ̀gbẹ́ kan,

      Ní ọjọ́ tí àwọn àjèjì mú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lẹ́rú,+

      Nígbà tí àwọn àjèjì gba ẹnubodè rẹ̀ wọlé, tí wọ́n sì ṣẹ́ kèké+ lórí Jerúsálẹ́mù,

      Ìwọ náà ṣe bíi tiwọn.

      12 Kò yẹ kí o fi ọmọ ìyá rẹ ṣe yẹ̀yẹ́ ní ọjọ́ tí àjálù bá a,+

      Kò yẹ kí o yọ̀ lórí àwọn ọmọ Júdà ní ọjọ́ tí wọ́n ń ṣègbé lọ,+

      Kò sì yẹ kí o máa fọ́nnu ní ọjọ́ wàhálà wọn.

      13 Kò yẹ kí o wọ ìlú* àwọn èèyàn mi ní ọjọ́ àjálù wọn,+

      Kò yẹ kí o fi í ṣe yẹ̀yẹ́ ní ọjọ́ àjálù rẹ̀,

      Kò sì yẹ kí o fọwọ́ kan ohun ìní rẹ̀ ní ọjọ́ àjálù rẹ̀.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́