-
1 Sámúẹ́lì 16:6, 7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Bí wọ́n ṣe wọlé, tí ó sì rí Élíábù,+ ó sọ pé: “Ó dájú pé ẹni àmì òróró Jèhófà ló dúró yìí.” 7 Ṣùgbọ́n Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Má wo ìrísí rẹ̀ àti bí ó ṣe ga tó,+ torí pé mo ti kọ̀ ọ́. Nítorí ọ̀nà tí èèyàn gbà ń wo nǹkan kọ́ ni Ọlọ́run gbà ń wo nǹkan, torí pé ohun tí ó bá hàn síta ni èèyàn ń rí, ṣùgbọ́n Jèhófà ń rí ohun tó wà nínú ọkàn.”+
-