-
Hébérù 11:32-34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
32 Kí ni kí n tún sọ? Torí àkókò ò ní tó tí n bá ní kí n máa sọ̀rọ̀ nípa Gídíónì,+ Bárákì,+ Sámúsìn,+ Jẹ́fútà,+ Dáfídì,+ títí kan Sámúẹ́lì+ àti àwọn wòlíì yòókù. 33 Ìgbàgbọ́ mú kí wọ́n ṣẹ́gun àwọn ìjọba,+ wọ́n mú kí òdodo fìdí múlẹ̀, wọ́n rí àwọn ìlérí gbà,+ wọ́n dí ẹnu àwọn kìnnìún,+ 34 wọ́n dáwọ́ agbára iná dúró,+ wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ojú idà,+ a sọ wọ́n di alágbára nígbà tí wọ́n jẹ́ aláìlera,+ wọ́n di akíkanjú lójú ogun,+ wọ́n mú kí àwọn ọmọ ogun ọ̀tá sá lọ.+
-