-
2 Àwọn Ọba 7:6, 7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Jèhófà ti mú kí ibùdó àwọn ará Síríà gbọ́ ìró àwọn kẹ̀kẹ́ ogun, ìró àwọn ẹṣin àti ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun.+ Torí náà, wọ́n sọ fún ara wọn pé: “Ẹ wò ó! Ọba Ísírẹ́lì ti háyà àwọn ọba àwọn ọmọ Hétì àti àwọn ọba Íjíbítì láti wá gbéjà kò wá!” 7 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n dìde, wọ́n sì sá lọ nígbà tí ilẹ̀ ti ṣú, wọ́n fi àwọn àgọ́ wọn àti àwọn ẹṣin wọn àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn sílẹ̀, gbogbo ibùdó náà wà bó ṣe wà, wọ́n sì sá lọ nítorí ẹ̀mí* wọn.
-