-
1 Àwọn Ọba 4:29-31Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 Ọlọ́run fún Sólómọ́nì ní ọgbọ́n àti òye tó pọ̀ gan-an àti ìjìnlẹ̀ òye tó pọ̀* bí iyanrìn etí òkun.+ 30 Ọgbọ́n Sólómọ́nì pọ̀ ju ọgbọ́n gbogbo àwọn ará Ìlà Oòrùn àti gbogbo ọgbọ́n Íjíbítì.+ 31 Ó gbọ́n ju èèyàn èyíkéyìí lọ, ó gbọ́n ju Étánì+ tó jẹ́ Ẹ́síráhì àti Hémánì,+ Kálíkólì+ àti Dáádà, àwọn ọmọ Máhólì; òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè tó yí i ká.+
-
-
2 Kíróníkà 1:10-12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Fún mi ní ọgbọ́n àti ìmọ̀+ tí màá fi máa darí àwọn èèyàn yìí,* nítorí ta ló lè ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn rẹ tó pọ̀ yìí?”+
11 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run sọ fún Sólómọ́nì pé: “Nítorí ohun tí ọkàn rẹ fẹ́ yìí àti pé o ò béèrè ọlá, ọrọ̀ àti ògo tàbí ikú* àwọn tó kórìíra rẹ, bẹ́ẹ̀ ni o ò béèrè ẹ̀mí gígùn,* àmọ́ o béèrè ọgbọ́n àti ìmọ̀ kí o lè máa ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn mi tí mo fi ọ́ jọba lé lórí,+ 12 màá fún ọ ní ọgbọ́n àti ìmọ̀; màá tún fún ọ ní ọlá àti ọrọ̀ àti iyì irú èyí tí àwọn ọba tó ṣáájú rẹ kò ní, kò sì ní sí èyí tó máa ní irú rẹ̀ lẹ́yìn rẹ.”+
-