-
Oníwàásù 2:4-8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Mo ṣe àwọn iṣẹ́ ńlá.+ Mo kọ́ àwọn ilé fún ara mi;+ mo gbin àwọn ọgbà àjàrà fún ara mi.+ 5 Mo ṣe àwọn ọgbà ọ̀gbìn àti ọgbà ìtura fún ara mi, mo sì gbin oríṣiríṣi igi eléso sínú wọn. 6 Mo ṣe àwọn adágún omi fún ara mi, láti máa fi bomi rin ọgbà* tí àwọn igi tó léwé dáadáa wà. 7 Mo ní àwọn ìránṣẹ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin,+ mo sì ní àwọn ìránṣẹ́ tí wọ́n bí ní agbo ilé mi.* Mo tún ní ọ̀pọ̀ ẹran ọ̀sìn, ìyẹn màlúù àti agbo ẹran,+ tó pọ̀ ju ti ẹnikẹ́ni tó wà ṣáájú mi ní Jerúsálẹ́mù. 8 Mo kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara mi,+ ìṣúra* àwọn ọba àti ti àwọn ìpínlẹ̀.+ Mo kó àwọn akọrin lọ́kùnrin àti lóbìnrin jọ fún ara mi, títí kan ohun tó ń múnú ọmọ aráyé dùn gidigidi, ìyẹn obìnrin, àní ọ̀pọ̀ obìnrin.*
-