-
Jeremáyà 50:41, 42Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
41 Wò ó! Àwọn èèyàn kan ń wọlé bọ̀ láti àríwá;
Orílẹ̀-èdè ńlá àti àwọn atóbilọ́lá ọba+ ni a ó gbé dìde
Láti àwọn ibi tó jìnnà jù lọ láyé.+
42 Wọ́n ń lo ọrun àti ọ̀kọ̀.*+
Ìkà ni wọ́n, wọn ò sì lójú àánú.+
Ìró wọn dà bíi ti òkun,+
Bí wọ́n ṣe ń gun ẹṣin wọn.
Bí ọkùnrin kan ṣoṣo ni wọ́n tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti gbógun tì ọ́, ìwọ ọmọbìnrin Bábílónì.+
-