ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 36:15, 16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn ń kìlọ̀ fún wọn nípasẹ̀ àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀, ó ń kìlọ̀ fún wọn léraléra, nítorí pé àánú àwọn èèyàn rẹ̀ àti ibùgbé rẹ̀ ń ṣe é. 16 Ṣùgbọ́n wọ́n ń fi àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ṣẹ̀sín,+ wọn ò ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí,+ wọ́n sì ń fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́,+ títí ìbínú Jèhófà fi ru sí àwọn èèyàn rẹ̀,+ tí ọ̀rọ̀ wọn sì kọjá àtúnṣe.

  • Àìsáyà 42:24, 25
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 Ta ló ti mú kí wọ́n kó ohun ìní Jékọ́bù,

      Tó sì mú kí wọ́n kó ẹrù Ísírẹ́lì?

      Ṣebí Jèhófà ni, Ẹni tí a ṣẹ̀?

      Wọ́n kọ̀ láti rìn ní àwọn ọ̀nà Rẹ̀,

      Wọn ò sì ṣègbọràn sí òfin* Rẹ̀.+

      25 Torí náà, Ó ń da ìhónú lé e lórí,

      Ìrunú rẹ̀ àti ìbínú ogun.+

      Ó jẹ gbogbo ohun tó yí i ká run, àmọ́ kò fiyè sí i.+

      Ó jó o, àmọ́ kò fọkàn sí i.+

  • Sekaráyà 1:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Inú bí mi gan-an sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ara tù,+ torí mi ò bínú púpọ̀ sí àwọn èèyàn mi,+ àmọ́ wọ́n dá kún àjálù náà.”’+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́