-
Àìsáyà 30:20, 21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà máa fi wàhálà ṣe oúnjẹ fún yín, tó sì máa fi ìyà ṣe omi fún yín,+ Olùkọ́ rẹ Atóbilọ́lá ò ní fi ara rẹ̀ pa mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀, o sì máa fi ojú ara rẹ rí Olùkọ́ rẹ Atóbilọ́lá.+ 21 Etí rẹ sì máa gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ pé, “Èyí ni ọ̀nà.+ Ẹ máa rìn nínú rẹ̀,” tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ yà sí apá ọ̀tún tàbí tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ yà sí apá òsì.+
-