12 Torí màá lọ káàkiri ilẹ̀ Íjíbítì lálẹ́ yìí, màá sì pa gbogbo àkọ́bí nílẹ̀ Íjíbítì, látorí èèyàn dórí ẹranko;+ màá sì dá gbogbo ọlọ́run Íjíbítì lẹ́jọ́.+ Èmi ni Jèhófà.
12 Màá sọ iná sí ilé* àwọn ọlọ́run Íjíbítì, ọba náà á sun wọ́n,+ á sì kó wọn lọ sí oko ẹrú. Á da ilẹ̀ Íjíbítì bora bí olùṣọ́ àgùntàn ti ń da ẹ̀wù bo ara rẹ̀, á sì jáde kúrò níbẹ̀ ní àlàáfíà.*
25 “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ pé: ‘Wò ó, màá yíjú sí Ámọ́nì+ láti Nóò*+ àti sí Fáráò àti Íjíbítì àti àwọn ọlọ́run rẹ̀+ àti àwọn ọba rẹ̀, àní màá yíjú sí Fáráò àti gbogbo àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e.’+
13 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èmi yóò tún pa àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* run, màá sì pa àwọn ọlọ́run Nófì*+ tí kò ní láárí run. Kò ní sí ọmọ Íjíbítì tó máa ṣe olórí* mọ́, màá sì mú kí ìbẹ̀rù wà ní ilẹ̀ Íjíbítì.+