-
Jeremáyà 25:22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 gbogbo ọba Tírè, gbogbo ọba Sídónì+ àti àwọn ọba erékùṣù tó wà ní ẹ̀gbẹ́ òkun,
-
-
Ìsíkíẹ́lì 26:3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Màá bá ọ jà, ìwọ Tírè, màá sì gbé ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè dìde sí ọ, bí òkun ṣe ń gbé ìgbì rẹ̀ dìde.
-
-
Jóẹ́lì 3:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Kí ló dé tí ẹ fi ṣe báyìí sí mi,
Tírè, Sídónì àti gbogbo ilẹ̀ Filísíà?
Ṣé mo ṣẹ̀ yín ni tí ẹ fi ń gbẹ̀san?
Tó bá jẹ́ ẹ̀san lẹ̀ ń gbà,
Ṣe ni màá yára dá a pa dà sórí yín láìjáfara.+
-
-
Émọ́sì 1:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,
‘Nítorí ìdìtẹ̀ mẹ́ta Tírè+ àti nítorí mẹ́rin, mi ò ní yí ọwọ́ mi pa dà,
Nítorí wọ́n kó gbogbo àwọn tí wọ́n mú nígbèkùn, wọ́n sì fà wọ́n lé Édómù lọ́wọ́,
Àti nítorí pé wọn kò rántí májẹ̀mú àwọn arákùnrin.+
10 Torí náà, màá rán iná sí ògiri Tírè,
Á sì jó àwọn ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò run.’+
-