-
Jeremáyà 34:18-20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Ohun tó sì máa ṣẹlẹ̀ nìyí sí àwọn tó da májẹ̀mú mi, tí wọn kò mú ọ̀rọ̀ májẹ̀mú tí wọ́n dá lójú mi ṣẹ, nígbà tí wọ́n gé ọmọ màlúù sí méjì, tí wọ́n sì gba àárín rẹ̀ kọjá,+ 19 ìyẹn, àwọn ìjòyè Júdà àti àwọn ìjòyè Jerúsálẹ́mù, àwọn òṣìṣẹ́ ààfin àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú gbogbo èèyàn ilẹ̀ náà tí wọ́n kọjá láàárín ọmọ màlúù tí wọ́n gé sí méjì náà: 20 Ṣe ni màá fà wọ́n lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn àti àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí wọn,* òkú wọn á sì di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹran orí ilẹ̀.+
-