ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 7:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Jèhófà máa mú gbogbo àìsàn kúrò lára rẹ; kò sì ní jẹ́ kí ìkankan nínú gbogbo àrùn burúkú tí o ti mọ̀ ní Íjíbítì ṣe ọ́.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo àwọn tó kórìíra rẹ ló máa fi àrùn náà ṣe.

  • Ìfihàn 21:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Ó máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn,+ ikú ò ní sí mọ́,+ kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.+ Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá lọ.”

  • Ìfihàn 22:1, 2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Ó wá fi odò omi ìyè+ kan hàn mí, tó mọ́ rekete bíi kírísítálì, tó ń ṣàn jáde láti ibi ìtẹ́ Ọlọ́run àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà  + 2 wá sí àárín ọ̀nà rẹ̀ tó bọ́ sí gbangba. Àwọn igi ìyè tó ń so èso méjìlá (12) sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì odò náà, wọ́n ń so èso lóṣooṣù. Ewé àwọn igi náà sì wà fún mímú àwọn orílẹ̀-èdè lára dá.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́