-
Jeremáyà 34:2, 3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Lọ bá Sedekáyà+ ọba Júdà sọ̀rọ̀, kí o sì sọ fún un pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Wò ó, màá fi ìlú yìí lé ọwọ́ ọba Bábílónì, á sì dáná sun ún.+ 3 Ìwọ kò sì ní lè sá mọ́ ọn lọ́wọ́, torí ó dájú pé wọ́n á mú ọ, wọ́n á sì fà ọ́ lé e lọ́wọ́.+ Ìwọ àti ọba Bábílónì máa rí ara yín, á sì bá ọ sọ̀rọ̀ lójúkojú, wàá sì lọ sí Bábílónì.’+
-
-
Jeremáyà 37:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Àwọn ará Kálídíà á sì pa dà wá, wọ́n á bá ìlú yìí jà, wọ́n á gbà á, wọ́n á sì dáná sun ún.”+
-