1Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ Jeremáyà,* ọmọ Hilikáyà, ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tó wà ní Ánátótì,+ ní ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì. 2 Jèhófà bá a sọ̀rọ̀ nígbà ayé Jòsáyà+ ọmọ Ámọ́nì,+ ọba Júdà, ní ọdún kẹtàlá tó ti ń jọba.
3 “Láti ọdún kẹtàlá ìjọba Jòsáyà+ ọmọ Ámọ́nì, ọba Júdà, títí di òní yìí, ọdún kẹtàlélógún rèé tí Jèhófà ti ń bá mi sọ̀rọ̀, léraléra ni mo sì ń bá yín sọ̀rọ̀,* ṣùgbọ́n ẹ kò fetí sílẹ̀.+