ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 14:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Ni mo bá sọ pé: “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Wò ó, àwọn wòlíì ń sọ fún wọn pé, ‘Ẹ kò ní rí idà, ìyàn kò sì ní dé bá yín, ṣùgbọ́n Ọlọ́run á fún yín ní àlàáfíà gidi ní ibí yìí.’”+

  • Jeremáyà 23:16, 17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí:

      “Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún yín.+

      Wọ́n ń tàn yín ni.*

      Ìran tó wá láti inú ọkàn wọn ni wọ́n ń sọ,+

      Kì í ṣe láti ẹnu Jèhófà.+

      17 Léraléra ni wọ́n ń sọ fún àwọn tí kò bọ̀wọ̀ fún mi pé,

      ‘Jèhófà ti sọ pé: “Ẹ máa ní àlàáfíà.”’+

      Wọ́n sì ń sọ fún gbogbo ẹni tó ní agídí ọkàn pé,

      ‘Àjálù kankan kò ní bá yín.’+

  • Jeremáyà 27:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì tó ń sọ fún yín pé, ‘Ẹ kò ní sin ọba Bábílónì,’+ nítorí èké ni wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín.+

  • Jeremáyà 28:1, 2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 28 Ní ọdún yẹn kan náà, ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekáyà+ ọba Júdà, ní ọdún kẹrin, ní oṣù karùn-ún, wòlíì Hananáyà ọmọ Ásúrì láti Gíbíónì+ sọ fún mi ní ilé Jèhófà lójú àwọn àlùfáà àti lójú gbogbo àwọn èèyàn náà pé: 2 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Màá ṣẹ́ àjàgà ọba Bábílónì.+

  • Ìdárò 2:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Ìran tí àwọn wòlíì rẹ rí fún ọ jẹ́ èké àti asán,+

      Wọn kò fi àṣìṣe rẹ hàn ọ́ láti gbà ọ́ lọ́wọ́ oko ẹrú,+

      Ṣùgbọ́n ìran tí wọ́n ń rí, tí wọ́n sì ń kéde fún ọ jẹ́ èké àti ìṣìnà.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́