ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 25:4-7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Wọ́n fọ́ ògiri ìlú náà wọlé,+ gbogbo ọmọ ogun sì sá gba ẹnubodè tó wà láàárín ògiri oníbejì nítòsí ọgbà ọba lóru, lákòókò yìí, àwọn ará Kálídíà yí ìlú náà ká; ọba sì sá gba ọ̀nà Árábà.+ 5 Àmọ́ àwọn ọmọ ogun Kálídíà lé ọba, wọ́n sì bá a ní aṣálẹ̀ tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò, gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ sì tú ká kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 6 Lẹ́yìn náà, wọ́n gbá ọba mú,+ wọ́n mú un wá sọ́dọ̀ ọba Bábílónì ní Ríbúlà, wọ́n sì dá a lẹ́jọ́. 7 Wọ́n pa àwọn ọmọ Sedekáyà níṣojú rẹ̀; Nebukadinésárì wá fọ́ ojú Sedekáyà, ó fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà dè é, ó sì mú un wá sí Bábílónì.+

  • Jeremáyà 52:7-11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Níkẹyìn, wọ́n fọ́ ògiri ìlú náà wọlé, gbogbo ọmọ ogun sì sá kúrò ní ìlú lóru, wọ́n gba ẹnubodè tó wà láàárín ògiri oníbejì nítòsí ọgbà ọba jáde kúrò nínú ìlú náà, lákòókò yìí, àwọn ará Kálídíà yí ìlú náà ká; wọ́n gba ọ̀nà Árábà lọ.+ 8 Àmọ́ àwọn ọmọ ogun Kálídíà lé ọba, wọ́n sì bá Sedekáyà+ ní aṣálẹ̀ tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò, gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ sì tú ká kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 9 Lẹ́yìn náà, wọ́n gbá ọba mú, wọ́n mú un wá sọ́dọ̀ ọba Bábílónì ní Ríbúlà ní ilẹ̀ Hámátì, ó sì dá a lẹ́jọ́. 10 Ọba Bábílónì pa àwọn ọmọ Sedekáyà níṣojú rẹ̀, ó sì tún pa gbogbo àwọn ìjòyè Júdà níbẹ̀ ní Ríbúlà. 11 Lẹ́yìn náà, ọba Bábílónì fọ́ ojú Sedekáyà,+ ó sì fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà dè é, ó mú un wá sí Bábílónì, ó sì fi í sẹ́wọ̀n títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́