-
Ìsíkíẹ́lì 25:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èrò ìkà tó wà lọ́kàn àwọn Filísínì* ti mú kí wọ́n máa wá bí wọ́n á ṣe gbẹ̀san kí wọ́n sì pani run, torí wọn ò yéé kórìíra.+ 16 Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Màá na ọwọ́ mi láti fìyà jẹ àwọn Filísínì,+ màá pa àwọn Kérétì rẹ́,+ màá sì run àwọn tó ṣẹ́ kù nínú àwọn tó ń gbé ní etí òkun.+
-
-
Sefanáyà 2:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Nítorí Gásà máa di ìlú tí a pa tì;
Áṣíkẹ́lónì á sì di ahoro.+
-
-
Sekaráyà 9:5, 6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Áṣíkẹ́lónì á rí i, ẹ̀rù á sì bà á;
Gásà yóò jẹ̀rora,
Bẹ́ẹ̀ náà ni Ẹ́kírónì, torí pé ìrètí rẹ̀ ti di ìtìjú.
Ọba kan yóò ṣègbé ní Gásà,
Ẹnì kankan kò sì ní gbé ní Áṣíkẹ́lónì.+
-