ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 28:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Àwọn Filísínì+ náà tún wá kó ẹrù àwọn èèyàn ní àwọn ìlú Ṣẹ́fẹ́là+ àti Négébù ti Júdà, wọ́n sì gba Bẹti-ṣémẹ́ṣì,+ Áíjálónì,+ Gédérótì, Sókò àti àwọn àrọko rẹ̀,* Tímúnà+ àti àwọn àrọko rẹ̀ pẹ̀lú Gímúsò àti àwọn àrọko rẹ̀; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé níbẹ̀.

  • Àìsáyà 9:11, 12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Jèhófà máa gbé àwọn elénìní Résínì dìde sí i,

      Ó sì máa ru àwọn ọ̀tá rẹ̀ sókè láti jagun,

      12 Síríà láti ìlà oòrùn àti àwọn Filísínì láti ìwọ̀ oòrùn,*+

      Wọ́n máa la ẹnu wọn, wọ́n á sì jẹ Ísírẹ́lì run.+

      Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíì yí pa dà,

      Àmọ́ ó ṣì na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti lù wọ́n.+

  • Àìsáyà 14:29
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 29 “Kí ẹnì kankan nínú rẹ má yọ̀, ìwọ Filísíà,

      Torí pé ọ̀pá ẹni tó ń lù ọ́ ti kán.

      Torí ejò olóró+ máa jáde látinú gbòǹgbò ejò,+

      Ọmọ rẹ̀ sì máa jẹ́ ejò oníná tó ń fò.*

  • Jeremáyà 47:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 47 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nìyí fún wòlíì Jeremáyà nípa àwọn Filísínì,+ kí Fáráò tó pa Gásà run.

  • Jóẹ́lì 3:4-6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Kí ló dé tí ẹ fi ṣe báyìí sí mi,

      Tírè, Sídónì àti gbogbo ilẹ̀ Filísíà?

      Ṣé mo ṣẹ̀ yín ni tí ẹ fi ń gbẹ̀san?

      Tó bá jẹ́ ẹ̀san lẹ̀ ń gbà,

      Ṣe ni màá yára dá a pa dà sórí yín láìjáfara.+

       5 Torí ẹ ti kó fàdákà àti wúrà mi,+

      Ẹ sì ti kó àwọn ìṣúra mi tó ṣeyebíye gan-an lọ sínú àwọn tẹ́ńpìlì yín;

       6 Ẹ ti ta àwọn èèyàn Júdà àti Jerúsálẹ́mù fún àwọn Gíríìkì,+

      Kí ẹ lè lé wọn jìnnà kúrò ní ilẹ̀ wọn;

  • Émọ́sì 1:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  6 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,

      ‘“Nítorí ìdìtẹ̀ mẹ́ta ti Gásà+ àti nítorí mẹ́rin, mi ò ní yí ọwọ́ mi pa dà,

      Nítorí wọ́n kó gbogbo àwọn èèyàn nígbèkùn,+ wọ́n sì fà wọ́n lé Édómù lọ́wọ́.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́