4 o máa pa òwe yìí sí ọba Bábílónì pé:
“Ẹ wo bí òpin ṣe dé bá ẹni tó ń fipá kó àwọn míì ṣiṣẹ́!
Ẹ wo bí ìfìyàjẹni ṣe wá sí òpin!+
5 Jèhófà ti kán ọ̀pá àwọn ẹni burúkú,
Ọ̀pá àwọn tó ń ṣàkóso,+
6 Ẹni tó ń fìbínú kan àwọn èèyàn lẹ́ṣẹ̀ẹ́ láìdáwọ́ dúró,+
Ẹni tó ń fi ìkannú tẹ àwọn orílẹ̀-èdè lórí ba, tó sì ń ṣe inúnibíni sí wọn láìṣíwọ́.+