3 “Ìgbà náà ni màá kó àwọn tó ṣẹ́ kù lára àgùntàn mi jọ láti gbogbo ilẹ̀ tí mo fọ́n wọn ká sí,+ màá sì mú wọn pa dà wá sí ibi ìjẹko wọn,+ wọ́n á máa bímọ, wọ́n á sì di púpọ̀.+
14 Èmi yóò bọ́ wọn ní ibi ìjẹko tó dáa, ilẹ̀ tí wọ́n á sì ti máa jẹko yóò wà lórí àwọn òkè gíga Ísírẹ́lì.+ Wọ́n á dùbúlẹ̀ síbẹ̀, níbi ìjẹko tó dáa,+ orí ilẹ̀ tó sì dáa jù lórí àwọn òkè Ísírẹ́lì ni wọ́n á ti máa jẹ ewéko.”