17Ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì méje tó ní abọ́ méje+ náà wá, ó sì sọ fún mi pé: “Wá, màá fi ìdájọ́ aṣẹ́wó ńlá tó jókòó lórí omi púpọ̀ hàn ọ́,+2 ẹni tí àwọn ọba ayé bá ṣe ìṣekúṣe,*+ tí a sì mú kí àwọn tó ń gbé ayé mu wáìnì ìṣekúṣe* rẹ̀ ní àmupara.”+
3 Gbogbo orílẹ̀-èdè ti kó sọ́wọ́ rẹ̀ torí wáìnì ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́* ti ìṣekúṣe* rẹ̀,+ àwọn ọba ayé sì bá a ṣe ìṣekúṣe,+ àwọn oníṣòwò* ayé sì di ọlọ́rọ̀ torí ó ń gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ lọ́nà tó bùáyà, kò sì nítìjú.”