-
2 Àwọn Ọba 17:13, 14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Jèhófà lo gbogbo wòlíì rẹ̀ àti gbogbo aríran+ rẹ̀ láti máa kìlọ̀ fún Ísírẹ́lì àti Júdà pé: “Ẹ kúrò nínú àwọn ọ̀nà búburú yín!+ Kí ẹ máa pa àwọn àṣẹ mi àti àwọn ìlànà mi mọ́, bó ṣe wà nínú gbogbo òfin tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín, tí mo sì fi rán àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sí yín.” 14 Àmọ́ wọn ò gbọ́, wọ́n sì ya alágídí bí* àwọn baba ńlá wọn tí kò ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà Ọlọ́run wọn.+
-
-
Jeremáyà 7:12-14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 “‘Àmọ́, ní báyìí ẹ lọ sí àyè mi ní Ṣílò,+ níbi tí mo mú kí orúkọ mi wà ní ìbẹ̀rẹ̀,+ kí ẹ sì wo ohun tí mo ṣe sí i nítorí ìwà búburú àwọn èèyàn mi, Ísírẹ́lì.+ 13 Ṣùgbọ́n ẹ̀ ń ṣe gbogbo nǹkan yìí,’ ni Jèhófà wí, ‘àní bí mo tiẹ̀ bá yín sọ̀rọ̀ léraléra,* ẹ kò fetí sílẹ̀.+ Mo sì ń pè yín ṣáá, ṣùgbọ́n ẹ kò dá mi lóhùn.+ 14 Bí mo ti ṣe sí Ṣílò, bẹ́ẹ̀ ni màá ṣe sí ilé tí a fi orúkọ mi pè,+ èyí tí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé+ àti sí ibi tí mo fún ẹ̀yin àti àwọn baba ńlá yín.+
-