ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 14:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Jèhófà wá sọ fún mi pé: “Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni àwọn wòlíì náà ń sọ ní orúkọ mi.+ Mi ò rán wọn, bẹ́ẹ̀ ni mi ò pàṣẹ fún wọn, mi ò sì bá wọn sọ̀rọ̀.+ Ìran èké àti ìwoṣẹ́ asán àti ẹ̀tàn ọkàn wọn ni wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín.+

  • Jeremáyà 28:15, 16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Wòlíì Jeremáyà wá sọ fún wòlíì Hananáyà+ pé: “Jọ̀wọ́, fetí sílẹ̀, ìwọ Hananáyà! Jèhófà kò rán ọ, àmọ́ o ti mú kí àwọn èèyàn yìí gbẹ́kẹ̀ lé irọ́.+ 16 Torí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Wò ó! Màá mú ọ kúrò lórí ilẹ̀. Ọdún yìí ni wàá kú, nítorí o ti mú kí àwọn èèyàn dìtẹ̀ sí Jèhófà.’”+

  • Ìsíkíẹ́lì 13:8, 9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 “‘Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “‘Torí ẹ ti parọ́ tí ẹ sì ń rí ìran èké, mo kẹ̀yìn sí yín,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”+ 9 Àwọn wòlíì tó ń rí ìran èké àti àwọn tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ máa jìyà lọ́wọ́ mi.+ Wọn ò ní sí lára àwọn èèyàn tí mo fọkàn tán; orúkọ wọn ò ní sí nínú àkọsílẹ̀ orúkọ ilé Ísírẹ́lì; wọn ò ní pa dà sórí ilẹ̀ Ísírẹ́lì; ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́