64 “Jèhófà máa tú ọ ká sáàárín gbogbo orílẹ̀-èdè, láti ìkángun kan ayé dé ìkángun kejì ayé,+ o sì máa ní láti sin àwọn ọlọ́run tí wọ́n fi igi àti òkúta ṣe níbẹ̀, àwọn ọlọ́run tí ìwọ àtàwọn baba ńlá rẹ kò mọ̀.+
9 Màá sọ wọ́n di ohun àríbẹ̀rù àti àjálù lójú gbogbo ìjọba ayé,+ màá jẹ́ kí wọ́n di ẹni ẹ̀gàn àti ẹni àfipòwe, ẹni ẹ̀sín àti ẹni ègún + ní gbogbo ibi tí màá fọ́n wọn ká sí.+