-
Nọ́ńbà 3:6-8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 “Jẹ́ kí ẹ̀yà Léfì+ wá síwájú, kí o sì ní kí wọ́n dúró níwájú àlùfáà Áárónì, kí wọ́n máa ṣe ìránṣẹ́+ fún un. 7 Kí wọ́n máa ṣe iṣẹ́ wọn ní àgọ́ ìjọsìn, èyí ni ojúṣe wọn fún un àti fún gbogbo àpéjọ náà níwájú àgọ́ ìpàdé. 8 Kí wọ́n máa bójú tó gbogbo ohun èlò+ àgọ́ ìpàdé, kí wọ́n sì máa ṣe iṣẹ́ tó jẹ mọ́ àgọ́ ìjọsìn,+ èyí ni ojúṣe wọn fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
-
-
1 Kíróníkà 9:22, 23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Gbogbo àwọn tí wọ́n yàn ṣe aṣọ́bodè ní àwọn ibi àbáwọlé jẹ́ igba ó lé méjìlá (212). Wọ́n wà ní ibi tí wọ́n tẹ̀ dó sí bí orúkọ wọn ṣe wà nínú àkọsílẹ̀ ìdílé wọn.+ Dáfídì àti Sámúẹ́lì aríran+ ló yàn wọ́n sí ipò ẹni tó ṣeé fọkàn tán tí wọ́n wà. 23 Àwọn àti àwọn ọmọ wọn ló ń ṣọ́ àwọn ẹnubodè ilé Jèhófà,+ ìyẹn ilé àgọ́.
-