ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 30:2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  2 Wọ́n lọ sí Íjíbítì+ láì fọ̀rọ̀ lọ̀ mí,*+

      Láti wá ààbò lọ sọ́dọ̀ Fáráò,*

      Kí wọ́n sì fi òjìji Íjíbítì ṣe ibi ìsádi wọn!

  • Àìsáyà 36:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Torí náà, Rábúṣákè sọ fún wọn pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ sọ fún Hẹsikáyà pé, ‘Ohun tí ọba ńlá, ọba Ásíríà sọ nìyí: “Kí lo gbọ́kàn lé?+

  • Àìsáyà 36:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Wò ó! Ṣé Íjíbítì tó dà bí esùsú* fífọ́ yìí lo gbẹ́kẹ̀ lé, tó jẹ́ pé bí èèyàn bá fara tì í, ṣe ló máa wọ àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, tí á sì gún un yọ? Bí Fáráò ọba Íjíbítì ṣe rí nìyẹn sí gbogbo àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé e.+

  • Jeremáyà 2:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Kí ló dé tí o fi fẹ́ gba ọ̀nà Íjíbítì+

      Láti lọ mu omi Ṣíhórì?*

      Kí sì nìdí tí o fi fẹ́ gba ọ̀nà Ásíríà+

      Láti lọ mu omi Odò?*

  • Jeremáyà 37:5-7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 Nígbà náà, àwọn ọmọ ogun Fáráò jáde kúrò ní Íjíbítì,+ àwọn ará Kálídíà tí wọ́n dó ti Jerúsálẹ́mù sì gbọ́ ìròyìn nípa wọn. Torí náà, wọ́n ṣígun kúrò ní Jerúsálẹ́mù.+ 6 Ìgbà náà ni Jèhófà bá wòlíì Jeremáyà sọ̀rọ̀, ó ní: 7 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Ohun tí ẹ máa sọ fún ọba Júdà, tó rán yín wá sọ́dọ̀ mi láti wádìí nìyí: “Wò ó! Àwọn ọmọ ogun Fáráò tó ń bọ̀ wá ràn yín lọ́wọ́ yóò ní láti pa dà sí Íjíbítì, ilẹ̀ wọn.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́