ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Sámúẹ́lì 15:22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Sámúẹ́lì wá sọ pé: “Ṣé àwọn ẹbọ sísun àti ẹbọ+ máa ń múnú Jèhófà dùn tó kéèyàn ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà? Wò ó! Ṣíṣe ìgbọràn sàn ju ẹbọ,+ fífi etí sílẹ̀ sì sàn ju ọ̀rá+ àgbò;

  • Òwe 21:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  3 Kí èèyàn ṣe ohun tó dára tí ó sì tọ́

      Máa ń mú inú Jèhófà dùn ju ẹbọ lọ.+

  • Àìsáyà 1:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 “Àǹfààní wo ni ọ̀pọ̀ ẹbọ yín ń ṣe mí?”+ ni Jèhófà wí.

      “Àwọn ẹbọ sísun yín tí ẹ fi àgbò+ ṣe àti ọ̀rá àwọn ẹran tí ẹ bọ́ dáadáa + ti sú mi,

      Inú mi ò dùn sí ẹ̀jẹ̀+ àwọn akọ ọmọ màlúù,+ ọ̀dọ́ àgùntàn àti ewúrẹ́.+

  • Míkà 6:6-8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  6 Kí ni màá mú wá síwájú Jèhófà?

      Kí sì ni màá mú wá tí mo bá wá tẹrí ba fún Ọlọ́run lókè?

      Ṣé odindi ẹbọ sísun ni màá gbé wá síwájú rẹ̀,

      Àwọn ọmọ màlúù ọlọ́dún kan?+

       7 Ṣé inú Jèhófà máa dùn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àgbò,

      Sí ẹgbẹẹgbàárùn-ún ìṣàn òróró?+

      Ṣé màá fi àkọ́bí mi ọkùnrin rúbọ torí ọ̀tẹ̀ tí mo dì,

      Àbí màá fi èso ikùn mi rúbọ torí ẹ̀ṣẹ̀ mi?*+

       8 Ó ti sọ ohun tó dára fún ọ, ìwọ ọmọ aráyé.

      Kí sì ni Jèhófà fẹ́ kí o ṣe?*

      Bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo,*+ kí o mọyì jíjẹ́ adúróṣinṣin,*+

      Kí o sì mọ̀wọ̀n ara rẹ+ bí o ṣe ń bá Ọlọ́run rẹ rìn!+

  • Mátíù 9:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Torí náà, ẹ lọ kọ́ ohun tí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí: ‘Àánú ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ.’+ Torí kì í ṣe àwọn olódodo ni mo wá pè, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”

  • Mátíù 12:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Ṣùgbọ́n ká ní ẹ mọ ohun tí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí ni, ‘Àánú ni mo fẹ́,+ kì í ṣe ẹbọ,’+ ẹ ò ní dá àwọn tí kò jẹ̀bi lẹ́bi.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́