12 Ó máa gbé àmì* kan sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè, ó sì máa kó àwọn tó fọ́n ká lára Ísírẹ́lì jọ,+ ó máa kó àwọn tó tú ká lára Júdà jọ láti ìkángun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé.+
19 sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Èmi yóò mú igi Jósẹ́fù, tó wà lọ́wọ́ Éfúrémù àti àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, èmi yóò sì fi wọ́n mọ́ igi Júdà; èmi yóò sọ wọ́n di igi kan ṣoṣo,+ wọn yóò sì di ọ̀kan ní ọwọ́ mi.”’