ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 147:2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 Jèhófà ń kọ́ Jerúsálẹ́mù;+

      Ó ń kó àwọn tí wọ́n fọ́n ká lára Ísírẹ́lì jọ.+

  • Àìsáyà 56:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ẹni tó ń kó àwọn tó fọ́n ká lára Ísírẹ́lì jọ,+ kéde pé:

      “Màá kó àwọn míì jọ sọ́dọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ sí àwọn tí a ti kó jọ tẹ́lẹ̀.”+

  • Ìsíkíẹ́lì 34:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Èmi yóò bójú tó àwọn àgùntàn mi bí olùṣọ́ àgùntàn tó rí àwọn àgùntàn rẹ̀ tó fọ́n ká, tó sì ń fún wọn ní oúnjẹ.+ Èmi yóò gbà wọ́n sílẹ̀ kúrò ní gbogbo ibi tí wọ́n fọ́n ká sí ní ọjọ́ ìkùukùu* àti ìṣúdùdù tó kàmàmà.+

  • Ìsíkíẹ́lì 34:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 “Màá wá èyí tó sọ nù,+ màá mú èyí tó rìn lọ pa dà wálé, màá fi aṣọ wé èyí tó fara pa, màá sì tọ́jú èyí tó rẹ̀ kó lè lágbára; àmọ́ èmi yóò pa èyí tó sanra àti èyí tó lágbára. Èmi yóò dá a lẹ́jọ́.”

  • Ìsíkíẹ́lì 37:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 “Kí o wá sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Èmi yóò mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n lọ, èmi yóò kó wọn jọ láti ibi gbogbo, èmi yóò sì mú wọn wá sórí ilẹ̀ wọn.+

  • Sefanáyà 3:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Wò ó! Ní àkókò yẹn, màá dojú ìjà kọ gbogbo àwọn tó ń pọ́n ọ lójú;+

      Màá gba ẹni tó ń tiro là,+

      Màá sì kó àwọn tó ti fọ́n ká jọ.+

      Màá sọ wọ́n di ẹni iyì àti olókìkí*

      Ní gbogbo ilẹ̀ tí ìtìjú ti bá wọn.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́