-
1 Àwọn Ọba 17:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 “Dìde, lọ sí Sáréfátì, ti Sídónì, kí o sì máa gbé ibẹ̀. Wò ó! Màá pàṣẹ fún opó kan níbẹ̀, pé kí ó máa gbé oúnjẹ wá fún ọ.”+ 10 Torí náà, ó dìde, ó sì lọ sí Sáréfátì. Nígbà tó dé ẹnu ọ̀nà ìlú náà, opó kan wà níbẹ̀ tó ń ṣa igi jọ. Torí náà, ó pè é, ó sì sọ pé: “Jọ̀wọ́, bá mi fi ife bu omi díẹ̀ wá kí n mu.”+
-
-
1 Àwọn Ọba 17:20-23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Ó ké pe Jèhófà pé: “Jèhófà Ọlọ́run mi,+ ṣé wàá tún mú àjálù bá opó tí mò ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀ ni, tí o fi jẹ́ kí ọmọ rẹ̀ kú?” 21 Lẹ́yìn náà, ó nà sórí ọmọ náà ní ìgbà mẹ́ta, ó sì ké pe Jèhófà pé: “Jèhófà Ọlọ́run mi, jọ̀wọ́, mú kí ẹ̀mí* ọmọ yìí sọ jí.” 22 Jèhófà gbọ́ ẹ̀bẹ̀ Èlíjà,+ ẹ̀mí* ọmọ náà sọ jí, ó sì yè.+ 23 Èlíjà gbé ọmọ náà, ó gbé e sọ̀ kalẹ̀ láti yàrá orí òrùlé wá sínú ilé, ó sì gbé e fún ìyá rẹ̀; Èlíjà wá sọ pé: “Wò ó, ọmọ rẹ yè.”+
-
-
2 Àwọn Ọba 4:13-17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún Géhásì pé: “Jọ̀ọ́, sọ fún un pé, ‘O ti ṣe wàhálà gan-an nítorí wa.+ Kí ni kí n ṣe fún ọ?+ Ṣé ohun kan wà tí o fẹ́ kí n bá ọ sọ fún ọba+ tàbí fún olórí àwọn ọmọ ogun?’” Àmọ́, obìnrin náà fèsì pé: “Àárín àwọn èèyàn mi ni mò ń gbé.” 14 Torí náà, Èlíṣà sọ pé: “Kí wá ni a lè ṣe fún un?” Géhásì bá sọ pé: “Mo rí i pé kò ní ọmọ kankan,+ ọkọ rẹ̀ sì ti darúgbó.” 15 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sọ pé: “Pè é wá.” Torí náà, ó pè é, obìnrin náà sì dúró lẹ́nu ọ̀nà. 16 Ó wá sọ pé: “Ní ìwòyí ọdún tó ń bọ̀, wàá fi ọwọ́ rẹ gbé ọmọkùnrin.”+ Àmọ́, obìnrin náà sọ pé: “Rárá, ọ̀gá mi, èèyàn Ọlọ́run tòótọ́! Má parọ́ fún ìránṣẹ́ rẹ.”
17 Ṣùgbọ́n, obìnrin náà lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan ní àkókò kan náà ní ọdún tó tẹ̀ lé e, gẹ́gẹ́ bí Èlíṣà ṣe sọ fún un.
-