ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Mátíù 12:1-8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Ní àkókò yẹn, Jésù gba oko ọkà kọjá ní Sábáàtì. Ebi wá ń pa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ya àwọn erín ọkà* jẹ.+ 2 Nígbà tí àwọn Farisí rí èyí, wọ́n sọ fún un pé: “Wò ó! Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ ń ṣe ohun tí kò bófin mu lọ́jọ́ Sábáàtì.”+ 3 Ó sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ ò tíì ka ohun tí Dáfídì ṣe nígbà tí ebi ń pa òun àti àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀?+ 4 Bó ṣe wọ ilé Ọlọ́run, tí wọ́n sì jẹ àwọn búrẹ́dì tí wọ́n ń gbé síwájú,*+ èyí tí kò bófin mu fún òun àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ láti jẹ, àfi àwọn àlùfáà nìkan?+ 5 Àbí ẹ ò tíì kà á nínú Òfin pé ní àwọn Sábáàtì, àwọn àlùfáà inú tẹ́ńpìlì sọ Sábáàtì di aláìmọ́, a ò sì dá wọn lẹ́bi?+ 6 Àmọ́ mo sọ fún yín pé ohun kan tó tóbi ju tẹ́ńpìlì lọ wà níbí.+ 7 Ṣùgbọ́n ká ní ẹ mọ ohun tí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí ni, ‘Àánú ni mo fẹ́,+ kì í ṣe ẹbọ,’+ ẹ ò ní dá àwọn tí kò jẹ̀bi lẹ́bi. 8 Torí Ọmọ èèyàn ni Olúwa Sábáàtì.”+

  • Lúùkù 6:1-5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Ní sábáàtì kan, ó ń gba oko ọkà kọjá, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń ya àwọn erín ọkà* jẹ,+ wọ́n sì ń fi ọwọ́ ra á.+ 2 Ni àwọn kan nínú àwọn Farisí bá sọ pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń ṣe ohun tí kò bófin mu lọ́jọ́ Sábáàtì?”+ 3 Àmọ́ Jésù fún wọn lésì pé: “Ṣé ẹ ò tíì ka ohun tí Dáfídì ṣe rí ni, nígbà tí ebi ń pa òun àti àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀?+ 4 Bó ṣe wọ ilé Ọlọ́run, tó gba àwọn búrẹ́dì tí wọ́n ń gbé síwájú,* tó sì jẹ ẹ́, tó tún fún àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ jẹ, èyí tí kò bófin mu fún ẹnì kankan láti jẹ, àfi àwọn àlùfáà nìkan?”+ 5 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ọmọ èèyàn ni Olúwa Sábáàtì.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́