-
Mátíù 10:2-4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Orúkọ àwọn àpọ́sítélì méjìlá (12) náà nìyí:+ Àkọ́kọ́, Símónì, tí wọ́n ń pè ní Pétérù+ àti Áńdérù+ arákùnrin rẹ̀; Jémíìsì ọmọ Sébédè àti Jòhánù+ arákùnrin rẹ̀; 3 Fílípì àti Bátólómíù;+ Tọ́másì+ àti Mátíù+ agbowó orí; Jémíìsì ọmọ Áfíọ́sì; àti Tádéọ́sì; 4 Símónì tó jẹ́ Kánánéánì;* àti Júdásì Ìsìkáríọ́tù, ẹni tó dalẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.+
-
-
Máàkù 3:14-19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Ó wá kó àwọn méjìlá (12) jọ,* ó tún pè wọ́n ní àpọ́sítélì, àwọn yìí ló máa wà pẹ̀lú rẹ̀, tó sì máa rán lọ wàásù, 15 wọ́n máa ní àṣẹ láti lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.+
16 Àwọn méjìlá (12)+ tó kó jọ* ni Símónì, tó tún pè ní Pétérù,+ 17 Jémíìsì ọmọ Sébédè àti Jòhánù arákùnrin Jémíìsì (ó tún ń pe àwọn yìí ní Bóánágè, tó túmọ̀ sí “Àwọn Ọmọ Ààrá”),+ 18 Áńdérù, Fílípì, Bátólómíù, Mátíù, Tọ́másì, Jémíìsì ọmọ Áfíọ́sì, Tádéọ́sì, Símónì tó jẹ́ Kánánéánì* 19 àti Júdásì Ìsìkáríọ́tù, ẹni tó dà á lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.
Lẹ́yìn náà, ó wọ inú ilé kan,
-