-
1 Àwọn Ọba 9:7, 8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 ṣe ni màá ké Ísírẹ́lì kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fún wọn,+ màá gbé ilé tí mo ti yà sí mímọ́ fún orúkọ mi sọ nù kúrò níwájú mi,+ Ísírẹ́lì yóò sì di ẹni ẹ̀gàn* àti ẹni ẹ̀sín láàárín gbogbo èèyàn.+ 8 Ilé yìí á di àwókù.+ Gbogbo ẹni tó bá gba ibẹ̀ kọjá á wò ó tìyanutìyanu, á súfèé, á sì sọ pé, ‘Kì nìdí tí Jèhófà fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí àti sí ilé yìí?’+
-
-
Jeremáyà 22:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 “‘Àmọ́ bí ẹ ò bá ṣe ohun tí mo sọ yìí, mo fi ara mi búra pé, ilé yìí máa di ahoro,’+ ni Jèhófà wí.
-