ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Mátíù 26:14-16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Lẹ́yìn náà, ọ̀kan nínú àwọn Méjìlá náà, tí wọ́n ń pè ní Júdásì Ìsìkáríọ́tù,+ lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà,+ 15 ó sì sọ pé: “Kí lẹ máa fún mi, kí n lè fà á lé yín lọ́wọ́?”+ Wọ́n bá a ṣe àdéhùn ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà.+ 16 Torí náà, látìgbà yẹn lọ, ó ń wá ìgbà tó máa dáa jù láti fà á lé wọn lọ́wọ́.

  • Máàkù 14:10, 11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Júdásì Ìsìkáríọ́tù, ọ̀kan nínú àwọn Méjìlá náà, lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà láti fà á lé wọn lọ́wọ́.+ 11 Inú wọn dùn nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n sì ṣèlérí pé àwọn máa fún un ní owó fàdákà.+ Torí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá ìgbà tó máa dáa jù láti fà á lé wọn lọ́wọ́.

  • Jòhánù 6:70
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 70 Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin méjìlá (12) yìí ni mo yàn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?+ Síbẹ̀, abanijẹ́* ni ọ̀kan nínú yín.”+

  • Jòhánù 13:2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 Wọ́n ń jẹ oúnjẹ alẹ́ lọ́wọ́, Èṣù sì ti fi sínú ọkàn Júdásì Ìsìkáríọ́tù,+ ọmọ Símónì, pé kó dà á.+

  • Jòhánù 13:27
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 27 Lẹ́yìn tí Júdásì gba búrẹ́dì náà, Sátánì wọ inú Júdásì.+ Torí náà, Jésù sọ fún un pé: “Tètè ṣe ohun tí ò ń ṣe kíákíá.”

  • Ìṣe 1:16, 17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, ó pọn dandan kí ìwé mímọ́ ṣẹ, èyí tí ẹ̀mí mímọ́ gba ẹnu Dáfídì sọ nípa Júdásì,+ ẹni tó ṣamọ̀nà àwọn tó wá mú Jésù.+ 17 Nítorí a ti kà á mọ́ wa,+ ó sì ní ìpín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́