-
2 Àwọn Ọba 4:32-34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
32 Nígbà tí Èlíṣà wọnú ilé náà, òkú ọmọ náà wà lórí ibùsùn rẹ̀.+ 33 Lẹ́yìn tó wọlé, ó ti ilẹ̀kùn, àwọn méjèèjì sì wà nínú ilé, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà.+ 34 Ó gorí ibùsùn, ó nà lé ọmọ náà, ó sì gbé ẹnu rẹ̀ lé ẹnu ọmọ náà àti ojú rẹ̀ lé ojú ọmọ náà, ó tún gbé àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ lé àtẹ́lẹwọ́ ọmọ náà, ó sì nà lé e lórí síbẹ̀, ara ọmọ náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í móoru.+
-