8 Mo gbé Jèhófà síwájú mi nígbà gbogbo.+
Torí pé ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, mìmì kan ò ní mì mí.+
9 Nítorí náà, ọkàn mi ń yọ̀, gbogbo ara mi ń dunnú.
Mo sì ń gbé lábẹ́ ààbò.
10 Torí o ò ní fi mí sílẹ̀ nínú Isà Òkú.+
O ò ní jẹ́ kí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ rí kòtò.+
11 O jẹ́ kí n mọ ọ̀nà ìyè.+
Ayọ̀ púpọ̀+ wà ní iwájú rẹ,
Ìdùnnú sì wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ títí láé.