-
Róòmù 5:10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Torí tó bá jẹ́ pé nígbà tí a jẹ́ ọ̀tá, ikú Ọmọ Ọlọ́run mú wa pa dà bá a rẹ́,+ ǹjẹ́ ààyè rẹ̀ kò ní mú ká rí ìgbàlà ní báyìí tí a ti pa dà bá a rẹ́?
-
-
Éfésù 2:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Ó lo ẹran ara rẹ̀ láti fòpin sí ọ̀tá náà, ìyẹn, Òfin tí àwọn àṣẹ àti ìlànà wà nínú rẹ̀, kí ó lè mú kí àwùjọ méjèèjì ṣọ̀kan pẹ̀lú ara rẹ̀, kí wọ́n lè di ẹni tuntun kan,+ kí ó sì mú àlàáfíà wá 16 àti pé kí ó lè mú àwùjọ méjèèjì wá sínú ara kan láti pa dà bá Ọlọ́run rẹ́ ní kíkún nípasẹ̀ òpó igi oró,*+ nítorí ó ti fúnra rẹ̀ pa ọ̀tá náà.+
-