ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 12:1-3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Jèhófà sì sọ fún Ábúrámù pé: “Kúrò ní ilẹ̀ rẹ, kí o kúrò lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ àti ilé bàbá rẹ, kí o lọ sí ilẹ̀ tí màá fi hàn ọ́.+ 2 Màá mú kí o di orílẹ̀-èdè ńlá, màá sì bù kún ọ. Màá mú kí orúkọ rẹ di ńlá, ó sì máa jẹ́ ìbùkún.+ 3 Màá súre fún àwọn tó ń súre fún ọ, màá sì gégùn-ún fún ẹni tó bá gégùn-ún fún ọ,+ ó dájú pé gbogbo ìdílé tó wà lórí ilẹ̀ yóò rí ìbùkún gbà* nípasẹ̀ rẹ.”+

  • Jẹ́nẹ́sísì 12:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Jèhófà wá fara han Ábúrámù, ó sì sọ pé: “Ọmọ* rẹ+ ni èmi yóò fún ní ilẹ̀ yìí.”+ Ó sì mọ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Jèhófà, ẹni tó fara hàn án.

  • Jẹ́nẹ́sísì 13:14, 15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Jèhófà sọ fún Ábúrámù lẹ́yìn tí Lọ́ọ̀tì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ pé: “Jọ̀ọ́ gbójú sókè níbi tí o wà, kí o sì wo àríwá àti gúúsù, ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn, 15 torí gbogbo ilẹ̀ tí o rí yìí ni màá fún ìwọ àti ọmọ* rẹ, yóò sì di ohun ìní yín títí láé.+

  • Jẹ́nẹ́sísì 17:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 “Màá mú májẹ̀mú mi ṣẹ, tí mo bá ìwọ+ àti ọmọ* rẹ dá jálẹ̀ gbogbo ìran wọn, pé màá jẹ́ Ọlọ́run fún ọ àti fún ọmọ* rẹ.

  • Jẹ́nẹ́sísì 22:17, 18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 ó dájú pé màá bù kún ọ, ó sì dájú pé màá mú kí ọmọ* rẹ pọ̀ bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti iyanrìn etí òkun,+ ọmọ* rẹ yóò sì gba ẹnubodè* àwọn ọ̀tá+ rẹ̀ lọ́wọ́ wọn. 18 Gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé yóò gba ìbùkún fún ara wọn nípasẹ̀ ọmọ*+ rẹ torí pé o fetí sí ohùn+ mi.’”

  • Jẹ́nẹ́sísì 24:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Jèhófà Ọlọ́run ọ̀run, ẹni tó mú mi kúrò ní ilé bàbá mi àti ilẹ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí+ mi, ẹni tó bá mi sọ̀rọ̀, tó sì búra fún mi+ pé: ‘Ọmọ*+ rẹ ni èmi yóò fún ní ilẹ̀ yìí,’+ yóò rán áńgẹ́lì rẹ̀ lọ ṣáájú rẹ,+ ó sì dájú pé wàá mú ìyàwó wá fún ọmọ mi láti ibẹ̀.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́