9 Torí ìdí yìí gan-an ni Ọlọ́run ṣe gbé e sí ipò gíga,+ tó sì fún un ní orúkọ tó lékè gbogbo orúkọ mìíràn,+10 kó lè jẹ́ pé ní orúkọ Jésù, kí gbogbo eékún máa wólẹ̀, ti àwọn tó wà lọ́run àti àwọn tó wà láyé pẹ̀lú àwọn tó wà lábẹ́ ilẹ̀,+
19 nítorí ó wu Ọlọ́run láti mú kí ohun gbogbo pé sínú rẹ̀,+20 kí ó sì lè tipasẹ̀ rẹ̀ mú gbogbo ohun mìíràn pa dà bá ara rẹ̀ rẹ́,+ ì báà jẹ́ àwọn ohun tó wà ní ayé tàbí àwọn ohun tó wà ní ọ̀run, bí ó ṣe fi ẹ̀jẹ̀ tó ta sílẹ̀ lórí òpó igi oró* mú àlàáfíà wá.+