2 Ó máa jáde wá bí ẹ̀ka igi+ níwájú rẹ̀, bíi gbòǹgbò látinú ilẹ̀ tó gbẹ táútáú.
Ìrísí rẹ̀ kò buyì kún un, kò sì rẹwà rárá;+
Tí a bá sì rí i, ìrísí rẹ̀ kò fà wá sún mọ́ ọn.
3 Àwọn èèyàn kórìíra rẹ̀, wọ́n sì yẹra fún un,+
Ọkùnrin tó mọ bí ìrora ṣe ń rí, tó sì mọ àìsàn dunjú.
Ó dà bí ẹni pé ojú rẹ̀ pa mọ́ fún wa.
Wọ́n kórìíra rẹ̀, a sì kà á sí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan.+