-
2 Tímótì 2:16-18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Àmọ́ yẹra fún àwọn ọ̀rọ̀ asán tó ń ba ohun mímọ́ jẹ́,+ torí ṣe ló máa ń mú kí èèyàn túbọ̀ jìnnà sí Ọlọ́run, 17 ọ̀rọ̀ wọn sì máa tàn kálẹ̀ bí egbò tó kẹ̀. Híméníọ́sì àti Fílétọ́sì wà lára wọn.+ 18 Àwọn ọkùnrin yìí ti yà kúrò nínú òtítọ́, wọ́n ń sọ pé àjíǹde ti ṣẹlẹ̀,+ wọ́n sì ń dojú ìgbàgbọ́ àwọn kan dé.
-
-
1 Jòhánù 2:18, 19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Ẹ̀yin ọmọdé, wákàtí ìkẹyìn nìyí, bí ẹ sì ṣe gbọ́ pé aṣòdì sí Kristi ń bọ̀,+ kódà ọ̀pọ̀ aṣòdì sí Kristi ló ti fara hàn báyìí,+ ìyẹn sì jẹ́ ká mọ̀ pé wákàtí ìkẹyìn nìyí lóòótọ́. 19 Wọ́n kúrò lọ́dọ̀ wa, àmọ́ wọn kì í ṣe ara wa;*+ torí ká ní wọ́n jẹ́ ara wa ni, wọn ò ní fi wá sílẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n kúrò lọ́dọ̀ wa kó lè hàn pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló jẹ́ ara wa.+
-