9 Àgọ́ yìí jẹ́ àpèjúwe fún àkókò yìí,+ a sì ń fi àwọn ọrẹ àti ẹbọ rúbọ ní ìbámu pẹ̀lú ètò yìí.+ Àmọ́ àwọn yìí ò lè mú kí ẹni tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ pátápátá.+
24 Torí Kristi ò wọnú ibi mímọ́ tí wọ́n fi ọwọ́ ṣe,+ tó jẹ́ àpẹẹrẹ ohun gidi,+ àmọ́ ọ̀run gangan ló wọ̀ lọ,+ tó fi jẹ́ pé ó ń fara hàn báyìí níwájú* Ọlọ́run nítorí wa.+